Ese Ifá Kòòkan
I.Èjì Ogbè
Ese èkíní
Até l’ó b’édun nlè,
Edun
ò mò on sá;
A diá fún edun,
Edun
tí í se omo ìyá àáyá.
Àáyá fò fèrè,
Ó g’orí ìgbá.
Edun
tá féré,
Edun
g’orí igi.
Nígbà tí ìwá sè;
Ilèélè ni àáyá máa n rìn
Òun pèlú edun,
Omo
iyá è.
Sùgbón
ní ojó kan,
Edun
àti àáyá wáá jalè,
Wón loo jí àgbàdo ya l’óko olóko.
Àáyá l’ó kó rí olóko,
L’ó bá fò fèrè gun igi igbá.
Nígbà tí edun ó fi wí pé òun ó fò;
Olóko ti dé,
Ó si mú edun.
Olóko wáá di edun lókùn
Nígbà tí ó mú un dé ilédì,
Wón rí i pé omo Òsùn ni.
Wón wáá so fún olóko pé
Eni tí o mú wá yìí,
Àwon ò gbodò pa á,
Nítori pé omo Òsùn ni.
Wón ní kí edun ó jéwó.
Ní edún bá jéwó.
Óní lóòótó ni òún ya àgbàdo,
Sùgbón
lójú olóko ni òún se ya á.
Wón wáá bi edun pé
Kin ni yóó san fún olóko.
Edún
wáá bèrè sí í se bíi wèrè.
Óní, ‘Edun yàgbàdo hàà;
Edún
yàgbàdo hàà.”
Ni àwon egbé Ìmùlé bá so
wí pé
Ti edún tán nbè.
Wón ní àáyá tí rí olóko sá
Ní kí won ó fì ìyà je.
Wón ní,’omo ìyá kan náà
Ni edún àti àáyá.
Sùgbón
won ò fi àwò joraa won.
Edún
bó nínú ejó,
Òrán sì kan àáyá,”
Àwon Ògbóni wáá ní
Ta ní ò tánràn araa won?
Wón ní,Ìwo edun,
Nígbà tí o mo ìwà àáyá,
Èé se tí ò jo fò fèrè?
Edún
gbálájá, emi l’o wáá sáré se?
Kín l’ó se tí o ò fi fò mógi?
Tí olóko fi wáá mú o?
Edún
ní, omodé ní í yára bí àsá,
Àgbà abikùn dèèrè bí àpò.
Aré b’édun nlè.
Edún
ò mò ón sá.
Aré orí igi l’ó yé edun.
Àáyá wá n fò sókè.
Edún
wá n bé.
Àáyá fò sókè,
Edún
bé.
Àáyá fò mógi lórùn,
Edún
sí, Edun lo.